Top 10 similar words or synonyms for aláyémọrẹ

okà    0.994432

tàánú    0.992532

òǹfà    0.992135

sùgọ    0.991969

ikin    0.991425

gbẹẹ    0.991220

àkàrà    0.991063

    0.990557

onísègùn    0.990245

àwò    0.990113

Top 30 analogous words or synonyms for aláyémọrẹ

Article Example
Ẹfọ̀n-Alààyè Nibi yìí ni Ẹ̀fọ̀n ti kún orúkọ Ọbalufọn Aláyémọrẹ. Lára Aláyémọrẹ ni wọn tí yọ Aláayè to fid i: Ẹ̀fọ̀n-Aláayè títí dí òní. Nígbà tí ó ṣe Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ ránṣẹ́ sí Ọ̀rànmíyàn kí o fi nǹkan ìtẹ̀lúdó ṣọwọ́ sí òun. Lẹ́yìn tí wọ́n ti fi nǹkan yìí ránṣẹ́ sí Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ; kò pẹ́ ti Ọ̀rànmíyàn kú. Àwọn ará Ilé-Ifẹ̀ wá ránṣẹ́ si Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ láti wá jọba lẹ́ẹ̀kejì. Kí o tó lọ, ó fí ọmọ rẹ̀ jọba ní ipò rẹ̀. Ìyàwó mẹ́ta ni Aláyémọrẹ ni kí ó tó kúrò ní Ẹ̀fọ̀n-Aláayè. Àwọn ni Adúdú Ọ̀ránkú tí ì ṣe ìran àwọn Obólógun; Aparapára ọ̀run ìran awọn Aṣemọjọ, ẹ̀ẹ̀kẹta ni Èsùmòrè-gbé-ojú-ọ̀run-sàgá-ìjà. Ìtàn sọ pé lásìkò tí Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ padà sí Ilé-Ifẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọọ̀ni, bọ́ sí àkókò ti Ọba Dàda Aláàfin Ọ̀yọ́ wá lórí oyè ni nǹkan bí 1200-1300AD.
Ẹfọ̀n-Alààyè Nínu ìtàn ìwáṣẹ̀ mìíràn, a gbọ́ pé Ọbàlùfọ̀n Aláyémore ni ọba àkọ́kọ́ ti o tẹ ìlú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè dó. Ọbalùfọ̀n Aláyémọrẹ yìí jẹ́ ọmọ Ọbàlùfọ̀n Ogbógbódirin tí í ṣe àkọ́bí Odùduwà tí ó jẹ́ Ọọ̀ni ti Ilé-Ifẹ̀ ni àkókó ìgbà kan. Lẹ́yìn Ikú rẹ̀, Ọ̀rànmíyàn lò yẹ kí ó jẹ ọba ní Ilé-Ifẹ̀ ṣùgbọ́n ó ti lọ sílùú àwọn ọmọ rẹ̀, Eweka ni Eìní ati Aláàfin ni Ọ̀yọ́. Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ ti jẹ oyè Ọọ̀ni kí Ọ̀rànmíyàn tó dé.
Ẹfọ̀n-Alààyè Nígbà tí Ọ̀rànmíyàn dé, Aláyẹ́mọrẹ sá kúrò lórí oyè nítorí pé ní ayé àtijọ́ wọn kì í fi ẹni ìṣááju sílẹ̀ láti fi àbúrò joyè. Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ rìn títí ó fi dé orí òkè kan. Wọn pe ibẹ̀ ni Ọba-òkè. Èyí ni ọba tó tẹ̀dó sorí òkè ṣùgbọ́n lónìí ọ̀bàkè ni wọn ń pe ibẹ̀.
Ẹfọ̀n-Alààyè Àkókò tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ rú ni lójú púpọ̀. Nínú ìtàn yìí a ri i pe Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ mọ àsìkò ti Ọ̀rànmíyàn wà láyé. A rí i pé ẹ̀gbọ́n àti àbúrò ni wọn. Kó yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ kó jẹ ọmọ àti bàbá. Lóòótọ́ ni Ọ̀rànmíyàn jẹ ọba ni Òkò, tó tún wá sí Ilé-Ifẹ̀. Àwọn ará Ọ̀y;ọ ló fi Àjàká jẹ ọba sí Òkò. Aláàfin Dada tí òpìtàn fẹnu bà pé ó jẹ ọba ní Ọ̀yọ́ da ìtàn rú. Johnson (1921:144) gbà pé Àjàká ló wá lórí oyè gẹ́gẹ́ bí Aláàfin Ọ̀yọ́ nígbà tí Ọ̀rànmíyàn kú. Tó bá jẹ́ òtítọ́ ní Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ tún wa jọba lẹ́ẹ̀kejì ní Ilé-Ifẹ̀ a jẹ́ pé àsìkò Aláàfin Àjàkáló jẹ ọba.
Ẹfọ̀n-Alààyè Awọn òtìtọ́ kọ̀ọ̀kan farahàn nínú ìtàn yìí. Lóòótọ́ ni Ọbalùfọ̀n Aláyémọrẹ kan wá ni Ilé-Ifẹ̀. Títí dí oní ọ̀gbọ́n Ọbàlùfọ̀n wa ní Ilé-Ifẹ̀. Àdúgbò Aláayè si wa ní Ilé-Ifẹ̀ títí dí òní. Kò sí irọ́ níbẹ̀ pé Ẹ̀fọ̀n Aláayè bá Ilé-Ifẹ̀ tan. Nínú ìtàn mìíràn, a gbọ pé àwọn oríṣìí ènìyàn bí i mẹ́fà ni wọ́n tẹ̀dó lásìkò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sí Ẹ̀fọ̀n-Aláayè. Nínú ìtàn yìí, a gbọ́ pé Èkúwì ló kọ́kọ́ dé sílùú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè, igbó-àbá ni Èkúwì tẹ̀dó sí. Ọdẹ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Oríkin náà tẹ̀dó sí Igbó àayè. Lọ́jọ́ kan, lásìkò tí oríkin tẹ̀dó, ó rí iná tó ń rú ni Igbó-Àbá. Ó ṣe ọ̀dẹ lọ sí igbó yìí. Oríkin rọ àwọn tó wa ni Igbó àbá kí wọn jọ má gbé ní Igbó-Àayè. Wọ́n gbà bẹ́ẹ̀. Lásìkò tí wọn jọ ń gbé ni wọn fí Ọbàlùfọ̀n jẹ ọba. Igbákejì Ọbàlùfọ̀n tí wọ́n jọ wá láti Ilé-Ifẹ̀ ní wọn fi jẹ igbákejì ọba tí a mọ̀ sí Ọbańlá. Bàbá Igbó Àbá ọjọ́sí ni wọn fi jẹ baba ọlọ́jà tí a mọ sí Ọbalọ́jà. Ọbàlùfọ̀n àti Ọbalọ́jà jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ nígbà náà. Bí ọba ṣe ń pàṣẹ fún àayè ní Ọbalọ́jà ṣe n pàṣẹ ní Ọ̀bàlú láyé ìgbà náà. Lónìí, Ọbalọ́jà jẹ Olóyè pàtàkì ní ìlú Ẹ̀fọ̀n. Ọbalọ́jù ní olórí àwọn Ọ̀bàlú. Àjọṣe wá láàrìn Ọba àti Ọbalọ́jà. Bí ọba kan bá wàjà ní ìlú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè, iwájú ilé ọba-ọlọ́ja ni wọn yóò kó ọjà lọ.